ORÍKÌS

ORÍKÌ AKỌGUN

  • Mò sún àálá
  • Mò rò ẹwà
  • Ọmọ ajagun jẹun
  • Ẹni tilè dé kò
  • Ó ní méèé gún'yán ọkọ
  • Méèé se ìsà àlè
  • Méèé wá un wẹ́wẹ́ k'ọkọ jẹ
  • Ó bọ́'kọ jà, ó p'adìẹ ọkọ jẹ
  • Í bé bà á ṣe bí ọkọ lónìí àgbò lòhun ò bá gbà
  • Bí mé rẹ'jẹ̀ lójú ẹmu
  • Mé jẹ́ mu mọ́ láyé
  • Ọmọ Akọgun
  • Ọmọ onítilédè, kọ́ ni sẹ̀ lé
  • Èrò mọ̀pá ní'kọ́gun
  • A firún ìgbín, a he'gba ahun
  • A gbẹ́'sẹ̀ kàn lérí aásọ, a gbé kan rẹ̀ lórí àkún
  • Ará igbó oríjà
  • Onígbómọláyè
  • Àyè mọ̀jà, àyè mọ̀jà

ORÍKÌ – KUOLE Kuole

  • Kúólé dà wọ́n rú
  • A dí nà má yà
  • Kúólé a dóo nú kojo
  • A jí rẹ́ ẹ̀rín ọ̀kínkín
  • Adàgbàlagbà ṣe yìn àgbìgbò
  • Ẹ róhun tó ṣ àgbò tó fi dẹ́kun ẹ̀rín rínrín
  • Tó bá ṣe igúnnugún
  • Á wo koko mó rí ẹyin
  • Tí a ò bá rí igúnnugún, a ó f òò dẹ̀ ṣ ẹbọ
  • Tí a ò bá rí àkàlàmọ̀gbò a ò gbọ́dọ̀ ṣ orò
  • Ìgbà ta kó ohun orò sílẹ̀ tán
  • Igún wọlé de, ó pa kuru m ẹ́bọ
  • Àkàlàmọ̀gbò ba lẹ̀ a j ẹ̀dọ̀
  • Tègìnríngé ba lẹ̀ ó jẹ̀ fun alákọni
  • Ọmọ Igún ńlá orí àkò
  • Ọmọ Àkàlàmọ̀gbò tí ń bẹ lóruù ebè
  • Àrè ọ̀jẹ́, ikú jẹ́ n nírá
  • Lágbòsógùn ọ̀jẹ́
  • A kìí d àgbà ọ̀jẹ̀, kí a má ní ọtí eégún n ílé

ORÍKÌ AÍLÙÚ

  • Ọmọ Aílùú tẹ̀ǹgàá
  • Ọmọ Olúpérún, Olúpégba
  • Ìyẹ́rẹ́ ni mí, mo dá wọ́ tá àgan n ílé Olówé
  • Ọmọ Olówé ni mí, mo re òsomọ̀jà
  • Mo t òkìtì Ẹ̀fọ̀n wáà soògùn l Ọ̀yọ́
  • Ọ̀yọ́ dùn, n ò re lé mọ́
  • Ó gbé arúgbó àlárúgbó rèé soògùn
  • Kálárúgbó ó pá arúgbó rẹ̀ mọ́
  • Èmi l ọmọ àá já wé di wé
  • Èmi la jáàgùn diì gùn
  • Oògùn tí ò jẹ́ ewé rẹ̀ ni ò pé
  • Iwọ ń bẹ n ílé bàbá mi
  • Mo ṣe wọ tán, mo mó jú le koko
  • Èmi l ọmọ àgbéré ọ̀gán, ọmọ ayòórò
  • Ọmọ ewé kan àá já s owó
  • Ọmọ igi gbogbo kìkì oògùn
  • Iwín ilé wa kì í ran ni
  • Wèrè ilé wa kì í ràn nìyàn
  • Èmi lọ̀sán pọ́n ganrí ganrí
  • Kọ́ ni mọ́ rìn de àágberí

Another Version

  • Omo Ailu te ga
  • Omo olu peru, omo olu pe gba
  • Omo Abi yo ka, to lonko
  • Omo bo ni lara O ju asolo
  • Emi lomo ibi-kodun, ka fowo wo
  • Towo, tileke la fi wo iran iye mi